Ilo AI kii ṣe ohun to jẹ tuntun fun imayedẹrun awa ẹda lode oni. Ṣaaju ChatGPT ni a ti n lo AI ni awọn ọna oriṣiriṣi bii ṣiṣe awari imọ nipasẹ Google, gbigba aba lori awọn oju-ewe ayelujara bii Amazon, Netflix ati bẹẹ bẹẹ lọ. Riran ti a n ran Siri ni iṣẹ, ilo AI naa ni. Eyi fi idi rẹ mulẹ pe ilo AI kii ṣe ohun tuntun. Amọ̀ dide ti ChatGPT dé ni o waa jẹ ki AI gbagbugbaja gan ni ni awujọ ayelujara.
Ẹ jẹ ki a wo diẹ ninu awọn ipa ti AI n ko ninu igbe aye ojoojumọ.
Nibi iṣẹ eto ilera, AI n ṣiṣẹ bii onimọ iṣegun pataki ti ó dantọ ti o si mọ niwọn tobẹ ti a le sọ sinu apo ṣokoto wa. Fun apẹẹrẹ, Google Health maa n ran awọn onimọ iṣegun lọwọ lati le ganni awọn arun bii arun jẹjẹrẹ lori ẹrọ X-ray kiakia ju ti tẹlẹ lọ. Ó da bii oju aranilọwọ ti o n ṣiṣẹ pẹlu dokita.
Iwulo AI ko gbẹyin rara nibi eto ẹkọ kikọ. Fun apẹẹrẹ, nibi eto ẹkọ ede kikọ, Duolingo maa n lo AI lati wadii ipele ti akẹẹkọọ kọọkan wa, ati ibi ti wọn ti n mẹhẹ. Nipa idi eyi, AI a ṣeto ẹkọ ti ọ yẹ olukaluku akẹẹkọọ fun wọn.
AI jẹ ọrẹ agbẹ nitori ipa takuntakun ti o n ko ninu eto ọgbin. Apẹẹrẹ ni AI kan ti orukọ rẹ n jẹ Blue River. Ó maa n ran awọn agbẹ lọwọ lati fin pakopako si ori igbo koriko nikan ṣoṣo lai pa awọn eweko lara. Eleyii a maa yọri si ilo pakopako lọna ti ko ni fi mu ijamba ba ayika ati agbegbe awa ẹda.
Awọn ẹrọ bii Alexa, Google Home ati Siri n ṣiṣẹ pẹlu agbara AI lati mu igbe aye dẹ eniyan lọrun ninu ile loriṣiriṣi ọna bii gbigbe orin soke fun gbigbọ, titan ina inu ilee ati pipa wọn, koda wọn a maa mu aba wa fun ina ounjẹ fun wiwa. Wọn dabi ẹrọ amugbalẹgbẹ ti o n ran eniyan lọwọ.
Biotilẹjẹ pe AI ti n di korikosun pẹlu igbe aye ode oni, ti o si n ran wa lọwọ loore koore, aaye si ṣi silẹ fun un lati yanranti si i, lojoojumọ si ni awọn onimọ n ṣiṣẹ le e lori siwaju si ki o le peye si i.
AI ṣe pataki, lilo rẹ naa si gba ọgbọn ki a ma ba le ṣi i lo.
Comments