top of page

Yorubafluent

Ogun Àgbáyé àkọ́kọ́


Ni ọsan ọjọ kan ni ọdun 1914, ọdọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Gavrilo Princip yi itan gbogbo agbaye pada. Ni ilu kan ti a n pe ni Sarajevo, ni orilẹ-ede Bosnia, ọmọkunrin naa ṣeku pa Franz Ferdinand, ẹni ti ó jẹ bii arole ọba  fun ilẹ Austria-Hungary. Idi ni pe awọn ara orílẹede Bosnia kò fẹ jẹ ẹka orilẹ-ede Austria Hungary, wọn fẹ darapọ mọ orilẹ-ede Serbia dipo rẹ. Iṣẹlẹ yii gan ni ó ṣana si rogbodiyan ogun agbaye kinni. 





Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe waa di rogbodiyan gbogbo agbaye? Ṣaaju iṣẹlẹ yii, awọn orilẹ-ede alagbara lagbaaye ti n padi apo pọ, ti wọ́n si n di rikiṣi si ara wọn. Koda, wọ́n n du kuuku laja sara wọn labẹlẹ, wọn si tun n ba ara wọn ṣe ọrẹ agidi. Ẹgbẹ akọkọ ni orilẹ-ede France, Russia ati Britain, ẹgbẹ ekeji ni orilẹ-ede Germany, Austria-Hungary ati Italy.


 Lẹyin iṣẹlẹ iṣekupani arole Austria-Hungary ti a mẹnu ba saaju, Austria-Hungary ba ṣide



ogun si Serbia. Russia sọ wipe oun yi o ti Serbia lẹyin, bẹẹ naa ni Germany tutọ soke, ó foju gba a wipe oun yi o ti Austria Hungary lẹhin. 


Aṣeyinwa asẹyinbọ, ija naa kuro ni ija Europe nikan, o di ija gbogbo agbaye nitori awọn orilẹ-ede agbaye bẹrẹ si ni gbe si ara wọn lẹyin, wọ́n fi ija pẹẹta. Ija naa di ija nla ti a n pe ni ogun agbaye ẹlẹẹkini nitori pe ija naa waye ni awọn apa ibikan ni Afirika, Asia ati Middle East. A wa ni ẹgbẹ meji gbankọgbankọ. Ẹgbẹ akọkọ jẹ France, Russia, Britain ti Italy ati Amẹrika darapọ mọ ni ọrẹhinrẹhin, a mọ ẹgbẹ yii si awọn Allies. Ẹgbẹ ekeji ti a mọ si Central powers, ni Germany, Austria Hungary, ijọba Ottoman ati Bulgaria ninu. 


Oju ija meji godogbo lo wa. Ni iwọ oorun, Germany ba France, Britain ati orilẹede America ja, ni ila orun German ati Austria Hungary ba Russia fi ija pẹẹta.





Inu koto ija ti a mọ si trenches ni pupọ ogun naa it waye ju. Ọpọlọpọ ẹmi lo si sọnu laarin ọdun 1914 si ọdun 1918 ti ija naa fi waye.



Wọ́n dẹkun ija jija ni ọdun 1918 nigbati awọn ẹgbẹ Central powers fi idi rẹmi. Ni ọdun 1919 awọn orilẹ-ede bu ọwọ lu adehun kan ti a n pe ni Treaty of Versailles. Eyi ṣe ami fun opin ogun naa.

38 views

Kommentarer


bottom of page